1Nígbà tí Dáfídì ọba di arúgbó, ọjọ́ rẹ̀ sì pọ̀, ara rẹ̀ kò le è móoru bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n da ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ bò ó.
2Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ẹ jẹ́ kí a wá ọ̀dọ́mọbìnrin wúndíá kan kí ó dúró ti ọba, kì ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Kí ó dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀ kí ara ọba OLÚWA wa lè móoru.”
3Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádo ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Ábíságì, ará Ṣúnémù, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba.
4Ọmọbìnrin náà rẹwà gidigidi; ó sì ń ṣe ìtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n ọba kò sì bá a lò pọ̀.
5Àdóníjà ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Hágátì sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì sètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀.
6(Baba rẹ̀ kò bà á nínú jẹ́ rí nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi hùwà báyìí?” Ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin, òun ni a bí lé Ábúsálómù.)
7Àdóníjà sì gbérò pẹ̀lú Jóábù, ọmọ Ṣérúyà àti Ábíátarì àlùfáà, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un.
8Ṣùgbọ́n Ṣádókù àlùfáà, Bẹ́náyà ọmọ Jóhóíádà, Nátanì wòlíì, Ṣímè àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rélì àti olórí ogun Dáfídì ni kò darapọ̀ mọ́ Àdóníjà
9Nígbà náà ni Àdóníjà fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rúbọ níbi òkúta Sóhélétì tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Énrógélì. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba.
10Ṣùgbọ́n kò pe Nátanì Wòlíì tàbí Bénáyà tàbí àwọn olórí tàbí Sólómónì arákùnrin rẹ̀.
11Nígbà náà ni Nátanì bèrè lọ́wọ́ Bátíṣébà, ìyá Sólómọ́nì pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Àdóníjà, ọmọ Hágítì ti jọba láìjẹ́ pé Dáfídì OLÚWA wa mọ̀ síi?
12Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Sólómónì.
13Lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ọba, kí o sì wí fún un pé, ‘OLÚWA mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, “Dájúdájú Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò Jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi?” Èéṣe nígbà náà tí Àdóníjà fi jọba?’
14Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ sì wà níbẹ̀, tí o sì ń bá ọba sọ̀rọ̀ èmi yóò wá, láti wádìí ohun tí o ti sọ.”
15Bẹ́ẹ̀ ni Bátíṣébà lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Ábíságì ará Súnémù sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba.
16Bátíṣébà sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba.
17Ó sì wí fún ọba pé, “OLÚWA mi; ìwọ fúnra rẹ fi OLÚWA Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: ‘Sólómónì ọmọ rẹ yóò jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi.’
18Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Àdóníjà ti di ọba, ìwọ, ọba OLÚWA mi, kò sì mọ̀ nípa rẹ̀.
19Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rúbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Ábíátarì àlùfáà àti Jóábù balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ.
20OLÚWA mi ọba, ojú gbogbo Ísírẹ́lì ń bẹ lára rẹ, láti mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ OLÚWA mi ọba lẹ́yìn rẹ.
21Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí OLÚWA mi ọba bá sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, wọn yóò sì ka èmi àti Sólómónì sí ẹlẹ́ṣẹ̀.”
22Bí ó sì ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Nátanì wòlíì sì wọlé.
23Wọ́n sì sọ fún ọba pé, “Nátanì wòlíì wà níbí.” Ó sì lọ ṣíwájú ọba, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀.
24Nátanì sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ, OLÚWA mi ọba, ti sọ pé Àdóníjà ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn rẹ àti pé òun ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ?
25Ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ ní òní, ó sì ti rúbọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran ọlọ́ràá àti àgùntàn. Ó sì ti pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, Balógun àti Ábíátarì àlùfáà. Ní sinsin yìí wọ́n ń jẹ wọ́n ń mu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Kí Àdóníjà ọba kí ó pẹ́!’
26Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti ṣádókù àlùfáà, àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóiádà, àti Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè.
27Ṣé nǹkan yìí ni OLÚWA mi ọba ti ṣe láìjẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ OLÚWA mi ọba lẹ́yìn rẹ?”
28Nígbà náà ni Dáfídì ọba wí pé, “Pe Bátíṣébà wọlé wá.” Ó sì wá ṣíwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀.
29Ọba sì búrá pé, “Dájúdájú bí OLÚWA ti wà ẹni tí ó ti gbàmí kúrò nínú gbogbo wàhálà,
30Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún yọ pé: Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi.”
31Nígbà náà ni Bátíṣébà tẹriba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, “Kí OLÚWA mi Dáfídì ọba kí ó pẹ́!”
32Dáfídì ọba sì wí pé, “Ẹ pe Sadókù àlùfáà wọlé fún mi àti Nátanì wòlíì àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà.” Nígbà tí wọ́n wá ṣíwájú ọba,
33Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ OLÚWA yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Sólómónì ọmọ mi kí ó gun ìbaka mi, kí ẹ sì mú-un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gíhónì.
34Níbẹ̀ ni Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì fi òróró yàn án ní ọba lórí Ísírẹ́lì. Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, ‘Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́!’
35Nígbà náà ni kí ẹ sì gòkè pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì wá, kí ó sì jókòó sórí ìtẹ́ mi, kí ó sì jọba ní ipò mi. Èmi ti yàn án ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.”
36Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì dá ọba lóhùn pé, “Àmín! Kí OLÚWA Ọlọ́run OLÚWA mi ọba, kéde rẹ̀ bẹ́ẹ̀
37Bí OLÚWA ti wà pẹ̀lú OLÚWA mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Sólómónì kí ó lè mú kí ìjọba rẹ̀ pẹ́ ju ìtẹ́ OLÚWA mi Dáfídì Ọba lọ!”
38Nígbà náà ni Sadókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóiádà, àwọn ará Kérétì àti Pélétì sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Sólómónì gun ìbaka Dáfídì ọba wá sí Gíhónì.
39Sádókù àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Sólómónì lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́!”
40Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn.
41Àdóníjà àti gbogbo awọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ipè, Jóábù sì wí pé, “Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí?”
42Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jónátanì ọmọ Ábíátarì àlùfáà sì dé, Àdóníjà sì wí pé, “Wọlé wá, ọkùnrin yíyẹ ìwọ gbọ́dọ̀ mú ìròyìn rere wá.”
43Jónátanì sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá, OLÚWA wa Dáfídì ọba ti fi Sólómónì jọba.
44Ọba sì ti rán Sádókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àti àwọn ará Kérétì àti Pélétì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbaka ọba,
45Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gíhónì. Lati ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́.
46Sólómónì sì ti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀.
47Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì ti tún wá láti bá OLÚWA wa Dáfídì Ọba yọ̀, wí pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ̀ mú orúkọ Sólómónì lókìkí ju tirẹ̀ lọ àti kí ìtẹ́ rẹ̀ kí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ!’ Ọba sì tẹ ara rẹ̀ ba lórí ibùsùn rẹ̀,
48ó sì wí pé, ‘Ògo ni fún OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí.’ ”
49Nígbà náà ni gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ Àdóníjà dìde ní ìdágìrì, wọ́n sì túká.
50Ṣùgbọ́n Àdóníjà sì bẹ̀rù Sólómónì, ó lọ, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.
51Nígbà náà ni a sì sọ fún Sólómónì pé, “Adóníjà bẹ̀rù Sólómónì Ọba, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí ọba Sólómónì búra fún mi lónìí pé, òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’ ”
52Sólómónì sì dáhùn pé, “Bí ó bá fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, irun orí rẹ̀ kan kì yóò sì bọ́ sílẹ̀; ṣùgbọ́n bí a bá rí búburú kan ní ọwọ́ rẹ̀ òun yóò kú.”
53Nígbà náà ni Sólómónì ọba rán àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú un sọ̀kalẹ̀ láti ibi pẹpẹ wá. Àdóníjà sì wá, ó sì foríbalẹ̀ fún Sólómónì ọba, Sólómónì sì wí pé, “Lọ ilé rẹ.”