1Ní àkókò náà Ábíjà ọmọ Jéróbóámù sì ṣàìsàn,
2Jéróbóámù sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́ ní aya Jéróbóámù. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣílò. Áhíjà wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jọba lórí àwọn ènìyàn yìí.
3Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì ṣọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.”
4Bẹ́ẹ̀ ni aya Jéróbóámù sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Áhíjà ní Ṣílò.
5Ṣùgbọ́n OLÚWA ti sọ fún Áhíjà pé, “Kíyèsí i, aya Jéróbóámù ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”
6Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Áhíjà sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jéróbóámù. Kíló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ.
7Lọ, sọ fún Jéróbóámù pé báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórì lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.
8Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, iwọ kò dàbí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi.
9Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn Ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbémi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.
10“ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jéróbóámù. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jéróbóámù, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Ísírẹ́lì. Èmi yóò mú ilé Jéróbóámù kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán.
11Ajá yóò jẹ ẹni Jéróbóámù tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní ìgbẹ́ ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. OLÚWA ti sọ ọ́!’
12“Níti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú.
13Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jéróbóámù, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ilé Jéróbóámù.
14“OLÚWA yóò gbé ọba kan dìde fún ra rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì tí yóò ké ilé Jéróbóámù kúrò. Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni? Àní nísinsìnyìí.
15OLÚWA yóò kọlu Ísírẹ́lì, yóò sì dà bí a ti ń mi ìyẹ́ nínú omi. Yóò sì fa Ísírẹ́lì tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò, nítorí wọ́n ti rú ìbínú OLÚWA nípa ṣíṣe ère òrìṣà.
16Yóò sì kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jéróbóámù ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.”
17Nígbà náà ni aya Jéróbóámù sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tírà. Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú.
18Wọ́n sì sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ábíjà wòlíì.
19Ìyòókù ìṣe Jéróbóámù, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì.
20Jéróbóámù sì jọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
21Réhóbóámù ọmọ Sólómónì sì jọba ní Júdà. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó sì jọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí OLÚWA ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà, ará Ámónì.
22Júdà sì ṣe búburú níwájú OLÚWA nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ.
23Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère àti igbó òrìṣà lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.
24Àwọn tí ń hùwà panṣágà sì tún ń bẹ ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí OLÚWA ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
25
26Ó sì kó ìṣúra ilé OLÚWA lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú aṣà wúrà tí Sólómónì ti ṣe.
27Réhóbóámù ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń sọ́ ilẹ̀kùn ilé ọba.
28Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé OLÚWA Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.
29Níti ìyókù ìṣe Réhóbóámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà bí?
30Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní ọjọ́ wọn gbogbo.
31Réhóbóámù sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dáfídì. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámá; ará Ámónì. Ábíjà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.