1Ó sì ṣe, ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Jéhù ọmọ Hánánì wá sí Bááṣà pé:
2“Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù, ó sì mú kí Ísírẹ́lì ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
3Nítorí náà, èmi yóò mú Bááṣà àti ile rẹ̀ kúrò, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jéróbóámù ọmọ Nébátì.
4Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Bááṣà tí ó bá kú ní ìlú, ẹyẹ ojú ọ̀run yóò sì jẹ àwọn tí ó kú ní oko.”
5Àti ìyókù ìṣe Bááṣà, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
6Bááṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní Tírísà. Élà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
7Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì wá nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì ọmọ Hánánì pẹ̀lú sí Bááṣà àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo búburú tí ó ti ṣe níwájú OLÚWA, ní mímú un bínú nípa ohun tó ti ṣe àti wíwà bí ilé Jéróbóámù: àti nítorí tí ó pa á run pẹ̀lú.
8Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Élà ọmọ Bááṣà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ní Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Tírísà ní ọdún méjì.
9Ṣímírì, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Élà sì wà ní Tírísà nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Árísà, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tírísà.
10Ṣímírì sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà, ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀.
11Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Bááṣà pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́.
12Bẹ́ẹ̀ ni Símírì pa gbogbo ilé Bááṣà run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó sọ sí Bááṣà nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì:
13nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Bááṣà àti Élà ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn.
14Ìyòókù ìṣe Élà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
15Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, ni Ṣímírì jọba ọjọ́ méje ní Tírísà. Àwọn ọmọ ogun sì dó ti Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì.
16Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó dó tì gbọ́ wí pé Símírì ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Ómírì, olórí ogun, bí ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọjọ́ náà ní ibùdó.
17Nígbà náà ni Ómírì àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gíbétónì, wọ́n sì dó ti Tírísà.
18Nígbà tí Ṣímírì sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú,
19nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú OLÚWA àti ní rírìn ní ọ̀nà Jéróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.
20Níti ìyókù ìṣe Ṣímírì, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísiírẹ́lì?
21Nígbà náà ní àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì dá sí méjì; apákan wọn ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn, láti fi í jọba, apákan tókù sì ń tọ Ómírì lẹ́yìn.
22Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Ómírì lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni Tíbínì kú, Ómírì sì jọba.
23Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Ómírì bẹ̀rẹ̀ sí ń jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tírisà.
24Ó sì ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Sérérì ní talẹ́ńtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samáríà, nípa orúkọ Sémérì, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà.
25Ṣùgbọ́n Ómírì sì ṣe búburú níwájú OLÚWA, Ó sì ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.
26Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jéróbóámù ọmọ Nébátì àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, láti fi ohun asán wọn mú OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.
27Ìyòókù ìṣe àti ohun tí ó ṣe, àti agbára rẹ tí ó fi hàn, a kò ha kọ, wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
28Ómírì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní Ṣamáríà. Áhábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
29Ní ọdún kejìdínlógójì Áṣà ọba Júdà, Áhábù ọmọ Ómírì jọba ní Isireli, o si jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún méjìlélógún.
30Áhábù ọmọ Ómírì sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.
31Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, ó sì mú Jésébélì, ọmọbìnrin Étíbáálì, ọba àwọn ará Sídónì ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Báálì, ó sì bọ ọ́.
32Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Báálì nínú ilé Báálì tí ó kọ́ sí Samáríà.
33Áhábù sì tún ṣe ère òrìṣà kan, ó sì ṣe púpọ̀ láti mú OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú ju èyí tí gbogbo ọba Ísírẹ́lì tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti ṣe lọ.
34