1Áhábù sì sọ gbogbo ohun tí Èlíjà ti ṣe fún Jésébélì àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì.
2Nítorí náà Jésébélì rán oníṣẹ́ kan sí Èlíjà wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.”
3Èlíjà sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Bíáṣébà ti Júdà, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀,
4nígbà tí òun tìkárarẹ̀ sì lọ ní ìrìn ojọ́ kan sí ihà, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, OLÚWA, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ”
5Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ.
6Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yínná, àti orù-omi wà lẹ́bá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀.
7Ańgẹ́lì OLÚWA sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jìn fún ọ.”
8Ó si dide, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Hórébù, òkè Ọlọ́run.
9Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀.
10
11OLÚWA sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú OLÚWA, nítorí OLÚWA fẹ́ ré kọjá.”
12Lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n OLÚWA kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá.
13Nígbà tí Èlíjà sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà.
14Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ májẹ̀mu rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.”
15OLÚWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí ihà Dámásíkù. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hásáélì ní ọba lórí Árámù.
16Tún fi òróró yan Jéhù ọmọ Nímísì ní ọba lórí Ísírẹ́lì, àti kí o fi òróró yan Èlíṣà ọmọ Sáfátì, ará Ábélí-Méhólà ní wòlíì ní ipò rẹ.
17Jéhù yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hásáélì, Èlíṣà yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jéhù.
18Ṣíbẹ̀, Èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (700) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Ísírẹ́lì, àní gbogbo eékún tí kò ì tíì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Báálì, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.”
19Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Èlíṣà ọmọ Sáfátì. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú ìkéjìlá. Èlíjà sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó.
20Nígbà náà ni Èlíṣà sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì ṣáré tọ Èlíjà lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
21Èlíṣà sì fi í sílẹ̀, ó padà ṣẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun-èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Èlíjà lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.