1Nígbà tí ọjọ́ ikú Dáfídì súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Sólómónì ọmọ rẹ̀.
2Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin,
3kí o sì wòye ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mósè, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ,
4kí OLÚWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsí ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’
5“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Jóábù ọmọ Ṣérúyà ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Ísírẹ́lì, sí Ábínérì ọmọ Nérì àti sí Ámásà ọmọ Jétérì. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.
6Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú ní àlàáfíà.
7“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Bárísíláì, ti Gílíádì, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Ábúsálómù arákùnrin rẹ̀.
8“Àti kí o rántí, Ṣíméhì ọmọ Gérà ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tí Báhúrímù wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Máhánáímù. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jọ́dánì, mo fi OLÚWA búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’
9Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, má ṣe kíyèsí í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”
10Nígbà náà ni Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì.
11Ó ti jọba lórí Ísírẹ́lì ní ogójì ọdún (40): ọdún méje (7) ni Hébúrónì àti ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) ní Jérúsálẹ́mù.
12
13Wàyìí, Àdóníjà ọmọ Hágítì tọ Bátíṣébà, ìyá Sólómónì wá. Bátíṣébà sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?”
14Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.”
15Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Ísírẹ́lì ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ OLÚWA wá.
16Nísinsìnyí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mí.”
17Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀ṣíwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Sólómónì ọba (Òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Ábíságì ará Súnémù ní aya.”
18Bátíṣébà sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.”
19Nígbà tí Bátíṣébà sì tọ Sólómónì ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Àdóníjà, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.
20Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi”
21Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Ábíságì ará Ṣúnémù fún Àdóníjà arákùnrin rẹ ní aya.”
22Sólómónì ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Ábíságì ará Súnémù fún Àdóníjà! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ni í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Ábíátarì àlùfáà àti fun Jóábù ọmọ Sérúíà!”
23Nígbà náà ni Sólómónì ọba fi OLÚWA búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí níyà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Àdóníjà kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí!
24Àti nísinsìnyí, bí ó ti dájú pé OLÚWA wà láàyè ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dáfídì àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Àdóníjà!”
25Sólómónì ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì kọlu Àdóníjà, ó sì kú.
26Ọba sì wí fún Ábíátarì àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Ánátótì, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsìn yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA níwájú Dáfídì baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.”
27Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì yọ Ábíátarì kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà OLÚWA, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ nípa ilé Élì ní Ṣílò ṣẹ.
28Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Jóábù, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Àdóníjà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Ábúsálómù, ó sì sá lọ sínú àgọ́ OLÚWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.
29A sì sọ fún Sólómónì ọba pé Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ OLÚWA àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Sólómónì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Johóíadà pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”
30Bénáyà sì wọ inú àgọ́ OLÚWA, ó sì wí fún Jóábù pé, “Ọba sọ wí pé, Jáde wá.”
31Ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọ lù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé bàbá mi, tí Jóábù ti ta sílẹ̀.
32OLÚWA yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dáfídì bàbá mi kò sì mọ̀ àwọn méjèèjì ni. Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ísírẹ́lì, àti Ámásà ọmọ Jétérì olórí ogun Júdà, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ.
33Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Jóábù àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dáfídì àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà OLÚWA wà títí láé.”
34Bẹ́ẹ̀ ni Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì gòkè lọ, ó sì kọlu Jóábù, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní ihà.
35Ọba sì fi Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ olórí ogun ní ipò Jóábù àti Sádókù àlùfáà ní ipò Ábíátarì.
36Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣíméhì ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn.
37Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.”
38Ṣíméhì sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí OLÚWA mi ọba ti wí.” Ṣíméhì sì gbé ní Jérúsálẹ́mù fún ìgbà pípẹ́.
39Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Síméì méjì sì sá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì ọmọ Máákà, ọba Gátì, a sì sọ fún Síméì pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gátì.”
40Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì ní Gátì láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Síméì sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gátì.
41Nígbà tí a sì sọ fún Sólómónì pé Síméì ti lọ láti Jérúsálẹ́mù sí Gátì, ó sì ti padà,
42Ọba pe Síméì lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti OLÚWA, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú’? Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’
43Èéṣe nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra OLÚWA mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?”
44Ọba sì tún wí fún Síméì pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dáfídì baba mi. Báyìí, OLÚWA yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ.
45Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Sólómónì ọba, ìtẹ́ Dáfídì yóò sì wà láìfòyà níwájú OLÚWA títí láéláé.”
46Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣíméhì, ó sì pa á.