Ìwé Àwọn Ọba Kìn-ín-ní 20:1-43 BYB2014 - Bible AI

1Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ. Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dóti Samáríà, ó sì kọlù ú.

2Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì wí:

3Sílífà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya re àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.”

4Ọba Ísírẹ́lì sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí OLÚWA mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ̀ ni.”

5Àwọn ońṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì sọ wí pé: ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.

6Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”

7Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”

8Àwọn àgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má se fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí o gbà fún un.”

9Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Bẹni-Hádádì pé, “Sọ fún OLÚWA mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Bẹni-hádádì.

10Bẹni-Hádádì sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Áhábù wí pé, “kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eekuru Samáríà yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”

11Ọba Ísírẹ́lì sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé: ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́rà halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ”

12Bẹni-Hádádì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nigbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ tẹgun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.

13Sì kíyèsí i, wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.’ ”

14Áhábù sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?” Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”

15Nígbà náà ni Áhábù ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbéríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n. (232) Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin. (700)

16Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Bẹni-Hádádì àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmúpara nínú àgọ́.

17Àwọn ìjòyè kékèké ìgbéríko tètè kọ́ jáde lọ.

17Bẹni-Hádádì sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samáríà jáde wá.”

18Ó sì wí pé, “Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láàyè; bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láàyè.”

19Àwọn ìjòyè kékèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbéríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn.

20Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Árámù sì sá, Ísírẹ́lì sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì sálà lórí ẹsin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin.

21Ọba Ísírẹ́lì sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Árámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

22Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Árámù yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”

23Àwọn ìránṣẹ́ ọba Árámù sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, Ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.

24Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe: Mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi olórí ogun sí ipò wọn.

25Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Ísírẹ́lì jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba ti wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

26Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Bẹni-Hádádì ka iye àwọn ará Árámù, ó sì gòkè lọ sí Áfékì, láti bá Ísírẹ́lì jagun.

27Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Árámù kún ilẹ̀ náà.

28Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Árámù rò pé OLÚWA, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA.’ ”

29Wọ́n sì dó ṣíwájú ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa ọ̀kẹ́ márùn ún (100,000) ẹlẹ́sẹ̀ nínú àwọn ará Árámù ní ọjọ́ kan.

30Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Áfékì, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàámẹ́talá-lé ẹgbẹ̀rún nínú wọn. Bẹni-Hádádì sì sá lọ sínú ìlú, ó sì fara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.

31Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”

32Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, Wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́kí èmi kí ó yè.’ ” Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láàyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”

33Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹni-Hádádì arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Bẹni-Hádádì jáde tọ̀ ọ́ wá, Áhábù sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.

34Bẹni-Hádádì sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Dámáskù, bí baba mi ti ṣe ní Samáríà.” Áhábù sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.

35Nípa ọ̀rọ̀ OLÚWA, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú.

36Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn OLÚWA gbọ́, kíyèsí i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.

37Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára.

38Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú.

39Bí ọba sì ti ń ré kọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárin ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbékùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mi rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san talẹ́ǹtì fàdákà kan.’

40Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.”

40Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ ti dá a.”

41Nígbà náà ni wòlíì náà yára, ó sì mú eérú kúrò ní ojú rẹ̀, ọba Ísírẹ́lì sì mọ̀ ọ́ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni ó ń ṣe.

42Ó sì wí fún ọba pé, “Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátapáta lọ́wọ́ lọ. Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀.’ ”

43Ọba Ísírẹ́lì sì lọ sí ilé rẹ̀ ní wíwú gbọ, inú rẹ sì bàjẹ́, ó sì wá sí Samáríà.

/article>