Ìwé Àwọn Ọba Kìn-ín-ní 3:1-28 BYB2014 - Bible AI

1Sólómónì sì bá Fáráò ọba Éjíbítì dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú-un wá sí ìlú Dáfídì títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹ́ḿpìlì OLÚWA, àti odi tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká.

2Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tíì kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA títí di ìgbà náà

3Sólómónì sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí OLÚWA nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dáfídì baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.

4ⓐ Ọba sì lọ sí Gíbíónì láti rúbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Sólómónì sì rú ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.

5Ní Gíbíónì OLÚWA fi ara han Sólómónì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”

6Sólómónì sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀ṣíwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.

7“Nísinsìnyìí, OLÚWA Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ̀ bí mo ṣe lè ṣe àwọn ojúṣe mi.

8Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrin àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mòye wọn.

9Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrin rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”

10Inú OLÚWA sì dùn pé Sólómónì béèrè nǹkan yìí.

11Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún-un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá,

12èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dà bí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dà bí rẹ lẹ́yìn rẹ.

13Ṣíwájú síi, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò bèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dà bí rẹ.

14Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dáfídì baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”

15Sólómónì jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.

15Ó sì padà sí Jérúsálẹ́mù, ó sì dúró níwájú àpótí májẹ̀mú OLÚWA, ó sì rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àṣè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.

16Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbérè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ.

17Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “OLÚWA mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀.

18Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí ẹlòmíràn ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.

19“Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e.

20Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ ti sùn lọ. Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi.

21Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi: ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì ríi pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.”

22Obìnrin kejì sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀.” Èyí òkú ni tirẹ̀; èyí alààyè ni tèmi. Ṣùgbọ́n èyí àkọ́kọ́ tún wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí òkú ni tìrẹ; èyí alààyè ni tèmi.” Báyìí ni wọ́n sì ń jiyàn níwájú ọba.

23Ọba sì wí pé, “Ẹni yìí wí pé, ‘Ọmọ mi ni ó wà láàyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú,’ nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láàyè.’ ”

24Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba.

25Ọba sì pàṣẹ pé: “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.”

26Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láàyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, OLÚWA mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ̀. Ẹ gé e sí méjì!”

27Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.”

28Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.

article>