1Sólómónì ọba sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.
2Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀:
3
4
5
6
7Sólómónì sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.
8Orúkọ wọn ni wọ̀nyí:
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20Àwọn ènìyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.
21Sólómónì sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ijọba láti odò Éjíbítì títí dé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì, àti títí dé etí ilẹ̀ Éjíbítì. Àwọn orílẹ̀ èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Sólómónì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
22Oúnjẹ Sólómónì fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n (30) ìyẹ̀fun kíkúná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun,
23Màlúù mẹ́wàá (10) tí ó sanra, àti ogún (20) màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti egbin, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.
24Nítorí òun ni ó ṣakóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Éfúrátì, láti Tífísà títí dé Gásà, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó káàkiri.
25Nígbà ayé Sólómónì, Júdà àti Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Béríṣébà, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.
26Sólómónì sì ní ẹgbàajì (40,000) ilé ẹsin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàafà (12,000) ẹlẹ́sin.
27Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Sólómónì ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá síbi tábìlì ọba, wọ́n sì ríi pé ohun kankan kò ṣẹ́ kù.
28Wọ́n tún máa ń mú ọkà báálì àti kóríko fún ẹsin àti fún ẹsin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.
29Ọlọ́run sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòrò òye tí a kò le è fi wé iyanrìn tí ó wà létí òkun.
30Ọgbọ́n Sólómónì sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Éjíbítì lọ.
31Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Étanì, ará Ésírà, àti Hémánì àti Kálíkólì, àti Darà àwọn ọmọ Máhólì lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀ èdè yíká.
32Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005).
33Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti Kédárì tí ń bẹ ní Lébánónì dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.
34Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀ èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì, tí àwọn ọba ayé ń rán, tí ó ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.