1Nígbà tí Hírámù ọba Tírè sì gbọ́ pé a ti fi òróró yan Sólómónì ní ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Sólómónì, nítorí ó ti fẹ́ràn Dáfídì ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.
2
3“Ìwọ mọ̀ pé Dáfídì bàbá mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí OLÚWA fi fi gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀ rẹ̀.
4Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí OLÚWA Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe.
5
6“Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi Kédárì Lébánónì fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Ṣídónì.”
7Nígbà tí Hárámù sì gbọ́ iṣẹ́ Sólómónì, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún OLÚWA lónìí, nítorí tí ó ti fún Dáfídì ní ọlọgbọ́n ọmọ láti sàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”
8Hírámù sì ránṣẹ́ sí Sólómónì pé:
9Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lébánónì wá sí òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi òkun títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.”
10Báyìí ni Hírámù sì pèsè igi Kédárì àti igi fírì tí Sólómónì ń fẹ́ fún un,
11Sólómónì sì fún Hírámù ní ẹgbàawá (20,000) òṣùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún (20) òṣùwọ̀n òróró dáradára. Sólómónì sì ń tẹ̀ṣíwájú láti ṣe èyí fún Hírámù lọ́dọọdún.
12OLÚWA sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrin Hírámù àti Sólómónì, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.
13Sólómónì ọba sì sa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Ísírẹ́lì; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ènìyàn (30,000).
14Ó sì rán wọn lọ sí Lébánónì, ẹgbàárún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lébánónì, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Ádónírámù ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.
15
16àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Sólómónì jẹ́ ẹgbẹ̀rindínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà.
17Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀.
18Àwọn oníṣọ̀nà Sólómónì àti Hírámù àti àwọn ènìyàn Gébálì sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.