1
2Ṣùgbọ́n Jéhóṣébà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù àti arábìnrin Áhásáyà, mú Jóásì ọmọ Áhásáyà, ó sì jí i lọ kúrò láàárin àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataláyà; Bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á.
3Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún OLÚWA fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataláyà fi jọba lórí ilẹ̀ náà.
4Ní ọdún kéje, Jéhóíádà ránṣẹ́ sí àwọn olóórí ní ọrọrún àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.
5Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún síṣọ́ ààfin ọba.
6Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn Ṣúrì, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní síṣọ́ ilé tí a kọ́,
7Àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yóòkù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún OLÚWA fún ọba.
8Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbúdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”
9Olórí àwọn ọrọọrún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jéhóíádà àlùfáà ti paà láṣẹ́. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jéhóíádà àlùfáà.
10Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn apata tí ó ti jẹ́ ti ọba Dáfídì tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.
11Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́báá pẹpẹ àti ilé ìhà gúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun OLÚWA náà.
12Jéhóíádà mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”
13Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.
14Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn ìjòyè àti àwọn afọ̀npè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀ wọ́n sì ń fọ̀npè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataláyà fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”
15Jéhóíádà àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrin àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.”
16Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin àti níbẹ̀ ni a ti pa á.
17Nígbà náà ni Jéhóíádà dá májẹ̀mú láàrin OLÚWA àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn OLÚWA. Ó dá májẹ̀mú láàrin ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú.
18Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mátanì àlùfáà Báálì níwájú àwọn pẹpẹ.
19Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọọrún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú àyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba.
20Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, pẹ̀lú ìlú ńlá náà sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí a pa Ataláyà pẹ̀lú idà náà ní ààfin.
21Jóásì jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.