1Ní ọdún kejì tí Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.
2
3Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLÚWA, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dáfídì baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ́lé àpẹrẹ baba a rẹ̀ Jóásì.
4Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.
5Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọin-gbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.
6Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mósè níbi tí OLÚWA ti paláṣẹ pé: “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
7
8
9Ṣùgbọ́n Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fèsì sí Ámásáyà ọba Júdà: “Òṣùṣù kan ní Lébánónì rán iṣẹ́ sí Kédárì ní Lébánónì, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú ìgbẹ́ ní Lébánónì wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀.
10Ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsìn yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lú?”
11Bí ó ti wù kí ó rí Ámásíà kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì sì dojúkọ ọ́. Òun àti Ámásáyà ọba Júdà kọjú sí ara wọn ní Bẹti-Ṣéméṣì ní Júdà.
12A kó ipa ọ̀nà Júdà nípasẹ̀ Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.
13Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì. Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600).
14Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ìdógò, ó sì dá wọn padà sí Ṣamáríà.
15Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jéhóásì, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?
16Jéhóásì sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Jéróbóámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
17
18Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Ámásáyà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?
19Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákísì, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lákísì, wọ́n sì pa á síbẹ̀.
20Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dáfídì.
21
22Òun ni ẹni tí ó tún Élátì kọ́, ó sì dá a padà sí Júdà lẹ́yìn tí Ámásáyà ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
23Ní ọdún kẹẹ̀dógún tí Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà, Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún.
24Ó ṣe búburú ní ojú OLÚWA kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì. Èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.
25Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Ísírẹ́lì padà láti Lebo-Hámátì sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jónà ọmọ Ámítaì, wòlíì láti Gátì Héférì.
26OLÚWA ti rí bí olúkúlùkù yálà ẹrú tàbí òmìnira, ti ń jìyà gidigidi; kò sì sí ẹnìkan tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
27Láti ìgbà tí OLÚWA kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Ísírẹ́lì láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì.
28Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéróbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn àṣeyọrí ológun rẹ̀ àti bí ó ṣe gbà padà fún Ísírẹ́lì lápapọ̀. Dámásíkù àti Hámátì, tí ó ti jẹ́ ní Yáúdì, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?
29Jéróbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àwọn ọba Ísírẹ́lì Ṣekaríyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.