1
2Heṣekáyà yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí OLÚWA pé,
3“Rántí, OLÚWA mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Heṣekáyà sunkún kíkorò.
4Kí ó tó di wí pé Àìṣáyà jáde kúrò ní àárin àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ OLÚWA wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé.
5“Lọ padà kí o sì sọ fún Heṣekáyà, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run baba rẹ Dáfídì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ: Èmi yóò wò ó sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsìnyìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.
6Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Ásíríà. Èmi yóò sì dábòbò ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’ ”
7Nígbà náà ni Àìṣáyà wí pé, “Mú ọ̀pọ̀tọ́ tí a sù bí i gàrí.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fi sí owo náà, ara rẹ̀ sì yá.
8Heṣekáyà sì béèrè lọ́wọ́ Àìṣáyà pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmìn pé OLÚWA yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”
9Àìṣáyà dáhùn pé, “Èyí ni àmìn tí OLÚWA fún ọ wí pé OLÚWA yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”
10“Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá,” Heṣekáyà wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”
11Nígbà náà wòlíì Àìṣáyà ké pe OLÚWA, OLÚWA sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Áhásì.
12Ní àkókò náà ni Méródákì-Báládánì ọmọ Báládánì ọba Bábílónì rán ṣẹ́ ìwé àti ẹ̀bùn sí Heṣekáyà nítorí tí ó ti gbọ́ nípa àìsàn Heṣekáyà.
13Heṣekáyà gba ìránṣẹ́ náà ó sì fi hàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti Ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò sì fi hàn wọ́n.
14Nígbà náà Àìṣáyà wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Heṣekáyà ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?”
15Wòlíì náà béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ní ààfin rẹ?”
16Nígbà náà Àìsáyà wí fún Heṣekáyà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA:
17Àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ Òní, wọn yí ó gbe lọ sí Bábílónì, kò sí ohun tí yóò kù, ni OLÚWA wí.
18Àti díẹ̀ nínú àwọn ilé rẹ, ẹran ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀, tí wọn yóò bí fún ọ, ni wọn yóò kó lọ, wọn yóò sì di ìwọ̀fà ní ààfin ọba Bábílónì.”
19“Ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ ó dára.” Heṣekáyà dáhùn. Nítorí ó rò wí pé, “Kò ha dára àlàáfíà àti òtítọ́ ní ọjọ́ ayé mi?”
20Ní ti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó kù nípa ìjọba Heṣekáyà, gbogbo ohun tí ó ṣe tan àti bí ó ti ṣe adágún omi àti ọ̀nà omi náà nípa èyí tí ó gbé wá omi sínú ìlú ńlá, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìgbéṣẹ̀ ayé àwọn ọba àwọn Júdà?
21Heṣekáyà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀: Mánásè ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.