Ìwé Àwọn Ọba Kejì 24:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà ìjọba Jéhóíákímù, Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì gbógun sí ilẹ̀ náà, Jéhóíákímù sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinéṣárì.

2OLÚWA sì rán àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Aráméánì, àwọn ará Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì. Ó rán wọn láti pa Júdà run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ nípaṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.

3Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Júdà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLÚWA, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe.

4Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí OLÚWA kò sì fẹ́ láti dáríjìn.

5Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóíákímù, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Júdà?

6Jéhóíákímù sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

7Ọba Éjíbítì kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Bábílónì ti gba gbogbo agbégbé rẹ̀ láti odò Éjíbítì lọ sí odò Éúférátè.

8ⓐ Jéhóíákínì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a sì máa jẹ́ Néhúṣítà ọmọbìnrin Élínátanì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

9Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.

10Ní àkókò náà àwọn ìjòyè Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì wá sílẹ̀ Jérúsálẹ́mù wọ́n sì gbé dófì kalẹ̀ fún un,

11Nebukadinéṣárì fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìjòyè fi ogun dótì í.

12Jéhóíákímù ọba Júdà àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.

12Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Bábílónì ó mú Jéhóíákínì ẹlẹ́wọ̀n.

13Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ Nebukadinéṣárì kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé OLÚWA àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì

14Ti kọ́ fún OLÚWA, Ó kó wọn lọ sí ìgbékùn gbogbo Jérúsálẹ́mù: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárún ún, àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.

15Nebukadinéṣárì mú Jéhóíákínì ní ìgbékùn lọ sí Bábílónì. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ile náà.

16Ọba Bábílónì àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) alágbára ọkùnrin, alágbára tí ó yẹ fún ogun, àti àwọn ẹgbẹ̀rùn (1000) oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ.

17Ó sì mú Mátanáyà arákùnrin baba Jéhóíákínì, ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ṣedekáyà.

18ⓑ Ṣedekáyà jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọbìnrin Jeremáyà; ó sì wá láti Líbínà.

19Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí Jéhóíákínì ti ṣe.

20Nítorí tí ìbínú OLÚWA, ni gbogbo èyí ṣe sẹ sí Jérúsálẹ́mù, àti Júdà, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

20Nísinsìn yìí Ṣedekíàyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.

cle>