1Námánì jẹ́ olórí ogun ọba Árámù. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ OLÚWA fún wa ní ìṣẹ́gun fún Árámù. Ó jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.
2Nísinsìnyìí ẹgbẹgbẹ́ láti Árámù ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Ísírẹ́lì, ó sì sin ìyàwó Námánì.
3Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samáríà! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
4Námánì lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ti sọ.
5“Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Árámù dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì.” Bẹ́ẹ̀ ni Námánì lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ talẹ́ńtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpàrọ̀ aṣọ mẹ́wàá.
6Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Námánì sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
7Bí ọba Ísírẹ́lì ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí àyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”
8Nígbà tí Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Ísírẹ́lì.”
9Bẹ́ẹ̀ ni Námánì sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Èlíṣà.
10Èlíṣà rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jọ́dánì, ẹran ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”
11Ṣùgbọ́n Námánì lọ pẹ̀lú ìbúnú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ OLÚWA Ọlọ́run, fi ọwọ́ọ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn.
12Ábánà àti Fápárì, odò Dámásíkù, dára ju gbogbo omi Ísírẹ́lì lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.
13Ìránṣẹ́ Námánì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòómélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!”
14Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jọ́dánì ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.
15Nígbà náà Námánì àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsìnyí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Ísírẹ́lì nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”
16Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò ní gba ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Námánì rọ̀ ọ́ láti gbàá, ó kọ̀.
17“Tí o kò bá ní gba,” Námánì wí pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí èmi, ìránṣẹ́ rẹ fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ẹrùpẹ̀ ìbaka méjì, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rúbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn ṣùgbọ́n OLÚWA.
18Ṣùgbọ́n kí OLÚWA kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rímónì láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rímónì, kí OLÚWA dáríji ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”
19Èlíṣà wí pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.”
20Géhásì, ìránṣẹ́ Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ̀ lórí Námánì, ará Árámù, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ńi ọwọ́ rẹ̀.”
21Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì sáré tẹ̀lé Námánì. Nígbà tí Námánì rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáadáa?” ó béèrè.
22“Gbogbo nǹkan wà dáadáa,” Géhásì dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Éfúráímù. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpàrọ̀ aṣọ méjì.’ ”
23Námánì wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Géhásì láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Géhásì.
24Nígbà tí Géhásì wá sí ilẹ̀ gíga, ó sì mú nǹkan náà lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì gbé wọn kúrò ní ilé, ó sì rán ọkùnrin náà jáde ó sì lọ.
25Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Èlíṣà.
26Ṣùgbọ́n Èlíṣà wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà-ólífì, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin?
27Ẹ̀tẹ̀ Námánì yóò rọ̀mọ́ ọ àti sí irú ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Géhásì kúrò níwájú Èlíṣà, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.