1Nítorí èyí náà ni èmi Pọ́ọ̀lù ṣe di òǹdè Jésù Kírísítì nítorí ẹ̀yin aláìkọlà,
2
3Bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni sókí,
4Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kírísítì.
5Èyí tí a kò í tíì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn àpostélì rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;
6
7Ìránṣẹ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fifún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.
8Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídi ọ̀rọ̀ Kírísítì fún àwọn aláìkọlà;
9
10Kí a bà á lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onirúuru ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,
11gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àtayébáyé tí ó ti pinnu nínú Kírísítì Jésù Olúwa wa:
12Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.
13Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, tíi ṣe ògo yín.
14Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eekún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.
15Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.
16Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ mú ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
17Kí Kírísítì lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́;
18Kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga náàìfẹ́ Kírísítì jẹ́.
19Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kírísitì yìí tí o ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọ́run kún yín.
20Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.
21Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kírísítì Jésù títí ìrandíran gbogbo, ayé àìnípẹ̀kun, Àmí.