Ìwé Àwọn Ará Éfésù 4:1-32 BYB2014 - Bible AI

1Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí.

2ⓐ Pẹ̀lu ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.

3Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.

4Ara kan ni ń bẹ, ati Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín.

5Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìtẹ̀bọmi kan.

6Ọlọ́run kan ati Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó se olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú gbogbo.

7Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kírísítì.

8ⓑ Nitorí náà a wí pé:

8“Nígbà tí ó gókè lọ sí ibi gíga, ó di ìgbékùn ni ìgbékùn, ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”

9(Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ” Kín ni ó jẹ́, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìhà ìṣàlẹ̀ ilẹ̀?

10Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.)

11Ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí àpósítélì; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí ajínyìnrere, àti àwọn mìíràn bí Olùṣọ́ àgàntàn àti olùkọ́ni.

12Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ fun iṣẹ́ ìráńṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kírísítì.

13Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kírísítì.

14Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni sìnà;

15ⓒ Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kírísítì.

16ⓓ Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípaṣẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkárárẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

17Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn.

18Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, àwọn tí ó sì di àjèjì sí ìwà-bí-Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí lílè ọkàn wọn.

19Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọ́ra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.

20Ṣùgbọ́n a kò fi Kírísítì kọ́ yín bẹ́ẹ̀.

21Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí otítọ́ ti ń bẹ nínú Jésù.

22Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ogbologbo ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ̀ bí ìfẹ́kúfẹ́ ẹ̀tàn;

23Kí ẹ sì di titun ni ẹ̀mí inú yín;

24Kí ẹ sì gbé ọkùnrin titun wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.

25ⓔ Nítorí náà ẹ fi èké ṣiṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwá jẹ́.

26Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí òòrùn wọ̀ bá ìbínú yín:

27Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè fún Èṣù.

28Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dara, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.

29Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdibàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí ti o dara fún ẹ̀kọ́, kí ó lè máa fi oore ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́.

30Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè.

31Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àránkan:

32Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkéjì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríji ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kírísítì ti dáríjì yín.

cle>