1
2
3Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín:
4Nínú gbogbo àdúrà mi fún-un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà,
5nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìn rere láti ọjọ́ kìn-ín-ni wá títí di ìsinsinyìí.
6
7
8Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jésù Kírísítì.
9Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti ṣíwájú síi nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,
10kí ẹ̀yin kí ó lè dà ohun tí ó dára jùlọ yàtọ̀ mọ̀, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ọjọ́ Kírísítì,
11tí ẹ sì kún fún èso òdodo tí ó ti ọ́dọ̀ Jésù Kírísítì wá—fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.
12
13
14Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni ẹ ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.
15Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kírísítì, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.
16Àwọn ti ìkẹ́yìn n fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a ó gbé mi dìde fún ìgbèjà ìyìn rere.
17Ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ẹ̀wẹ̀ ń fi ìlépa ara ẹni ń wàásù Kírísítì, kì í ṣe pẹ̀lú òótọ́ inú, wọn ń gbérò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi ni.
18Ṣùgbọ́n ohun tí ó sa ṣe pàtàkì ni pé, bóyá a wàásù pẹ̀lú ètè tó dára tàbí èyí tí kò dára, a ṣsá ń wàásù Kírísítì. Èyí sì ni ayọ̀ mi.
19
20
21
22Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì wà láàyè nínú ara, èyí yóò jásí èrè fún iṣẹ́ mi. Síbẹ̀, kíni èmí yóò yàn? Èmi kò mọ̀?
23Mo wà ní agbede méjì. Mo fẹ́ràn láti wà pẹ̀lú Kírísítì, èyí tí ó dára jùlọ.
24Ṣùgbọ́n ó ṣe iyebíye fún yín kí èmi kí ó wà nínú ara.
25Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́,
26kí ìbádàpọ̀ mi pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kan si le ru ayọ̀ yín sókè nínú Kírísítì nítorí mi.
27Ohun tó wù kí ó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ yín wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyìnrere Kírísítì. pé yálà bí mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin sì jùmọ̀ n jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìn rere, pẹ̀lú ọkàn kan;
28
29Nítorí a ti fi fún yín nítorí Kírísítì, kì í ṣe láti gbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.
30