Ìwé Àwọn Ará Fílípì 2:1-30 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànlé nítorí pé ìwọ wà ní ìsọ̀kan pẹ̀lú Kírísítì, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà,

2síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìsọ̀kan yín, níní ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà.

3ⓑ Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa-ara tàbí ògo asán, sùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ.

4Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.

5ⓒ Ìṣe yín gbọdọ̀ dàbí ti Kírísítì Jésù:

6Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run, kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.

7Ṣùgbọ́n kò ka ara rẹ̀ sí ohunkóhun, ó sì gba àbùdá ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.

8Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, Ó sì tẹríba títí di ojú ikú, àní ikú àgbélébùú.

9ⓓ Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ìpele tí ó ga jùlọ, ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ:

10Pé ni orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

11Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jésù Kírísítì ni Olúwa, fún ògo Ọlọ́run Baba.

12Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́ràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárin yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì,

13ⓔ Nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀

14Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí kíkùn àti ìjiyàn.

15ⓕ Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, mọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrin oníwà wíwọ́ àti alárèékérekè orílẹ̀-èdè láàrin àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé.

16Bí ẹ sì se di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kírísítì pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.

17Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú.

18Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.

19Mo ni ìrètí nínú Jésù Olúwa, láti rán Tìmótíù sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúrò yín.

20Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyan yín.

21Nítorí gbogbo wọn ni ó tọ́jú nǹkan ti ara wọn, kì í ṣe àwọn nǹkan ti Jésù Kírísítì.

22Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé Timotiu pedegé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀, nínú iṣẹ́ ìyìnrere.

23Nítorí náà, mo ní ìrètí láti rán sí yín ní àìpẹ́ tí mo bá wòye bí yóò ti rí fún mi.

24Ṣùgbọ́n mo ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, pé èmi tikarami pẹ̀lú yóò wá ní àìpẹ́.

25Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epáfíródítù arákùnrin mi sí yín, àti olùbá ṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹ́gbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi.

26Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn.

27Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́.

28Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù.

29Nítorí náà, ẹ fi ayọ̀ púpọ̀ gbà á nínú Olúwa; kí ẹ sì máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.

30Nítorí iṣẹ́ Kírísítì ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wé wu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.

icle>