Ìwé Àwọn Ará Fílípì 3:1-21 BYB2014 - Bible AI

1Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ àìléwu.

2Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́-búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà.

3ⓐ Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kírísítì Jésù, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran ara.

4ⓑ Bí èmi tìkárami pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara.

4Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀:

5Ẹnii tí a kọ nílà ní ijọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Ísírẹ́lì wá, láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù láti inú Hébérù wá; nítorí, ní ti òfin Farisí ni èmi;

6Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibínu sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.

7Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kírísítì.

8Nítòótọ́ láìṣe àní-àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kírísítì Jésù Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní láárí, kí èmi lè jèrè Kírísítì,

9Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkarami, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kírísítì, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́;

10Kí èmi lè mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábàápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá faramọ́ ọn nínú ikú rẹ̀;

11Bí ó lè ṣe é ṣe kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.

12Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa ǹṣó, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mí mú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kírísítì Jésù wá.

13Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwáju.

14Èmi ń lépa láti dé òpin aré-ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù.

15Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fi hàn yín.

16Kìkì pé, ibi tí a ti dé ná, ẹ jẹ́ kí a máa rìn ní ojú-ọ̀nà kan náà, kí a ni èrò kan náà.

17ⓒ Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ.

18Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúùgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsinyìí, pé, ọ̀ta àgbélébùú Kírísítì ni wọ́n:

19Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé.

20Nítorí ìlú-ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ lọ́run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jésù Kírísítì Olúwa.

21ⓓ Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

icle>