1Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi.
2Èmi ń bẹ̀ Éúódíà, mo sì ń bẹ Síńtíkè, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa.
3
4Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.
5Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòòsí.
6
7Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín máa nínú Kírísítì Jésù.
8Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òótọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.
9
10
11Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀.
12Mo mọ̀ bí a ti ṣe ń rẹ ara sílẹ̀, mo sì mọ̀ bí a ti ń di púpọ̀: ni ohunkóhun àti ní ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó àti láti wà ni àìjẹ, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní.
13
14Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú mi.
15Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Fílípì, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìn rere, nígbà tí mo kúrò ni Makedóníà, kò sí Ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábàápín ní ti gbígbà àti fífúnni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo.
16
17Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín
18Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì kún nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Ẹ́páfíródítù tí a ti rán wá lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórún dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run.
19Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kírísítì Jésù.
20Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.
21Ẹ kí olukùlùkù ènìyàn-mímọ́ nínú Kírísítì Jésù. Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín.
22Gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Késárì.
23