Ìwé Àwọn Ará Gálátíà 1:1-24 BYB2014 - Bible AI

1Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jésù Kírísítì àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.

2Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,

2Sí àwọn ìjọ ní Gálátíà:

3ⓐ Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa,

4ⓑ ẹni tí ó fí òun tìkararẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,

5ⓒ ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

6Ẹnu yà mi nítorí tí pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kírísítì, sí ìyìn rere mìíràn:

7èyí tí kì í ṣe ìyìn rere rárá. Ìdánilójú wà pé àwọn kan wà tí wọ́n ń sì yín lọ́nà, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìn rere Kírísítì padà.

8ⓓ Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí ańgẹ́lì kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

9Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsinyìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

10ⓔ Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kírísítì.

11ⓕ Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìn rere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn.

12N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì.

13ⓖ Nítorí ẹ̀yin ti gbúrò ìwà-ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́:

14ⓗ Mo sì ta ọ̀pọlọ́pọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrin àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.

15ⓘ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.

16Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù rẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,

17bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerúsálémù tọ àwọn tí í ṣe Àpósítélì ṣáájú mi: ṣùgbọ́n mo lọ sí Árábíà, mo sì tún padà wá sí Dámásíkù.

18ⓙ Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerúsálémù láti lọ kì Pétérù, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún,

19Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ Àpósítélì, bí kò ṣe Jákọ́bù arákùnrin Olúwa.

20Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí kíyèsí i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.

21Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Síríà àti ti Kílíkáíà;

22Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kírísítì ni Jùdíà:

23Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsìn yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.”

24Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

ticle>