1Nítorí òfin, bí o ti ní òjìjì àwọn ohun rere ti ń bẹ̀ tí kì í ṣe àwòrán tóòtọ́ fún rere nǹkan náà, kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbàgbogbo lọdọ́ọ̀dún mu àwọn tí ń wá sibẹ̀ di pípé.
2Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a ba ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.
3Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìranti ẹ̀ṣẹ̀ lọdọ́ọ̀dún.
4Nítorí ko ṣeeṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.
5
6
7
8Nígbà tí o wí ni ìṣáajú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọ̀rẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).
9Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsí i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” O mu ti ìṣáaju kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.
10Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jésù Kírísítì fi ara rẹ̀ rú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.
11Àti olukulùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé:
12
13Láti ìgbà náà, ó rétí títí a o fi àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣe àpótí itísẹ̀ rẹ̀.
14Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.
15Ẹ̀mí mímọ́ sì ń jẹri fún wa pẹ̀lú: Nítorí lẹ̀yìn tí ó wí pé,
16
17
18Ṣùgbọ́n níbi tí ìmukúrò ìwọ̀nyí bá gbé wà, ìrubọ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́.
19Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù,
20Nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọja aṣọ ìkelé èyí yìí ní, ara rẹ̀;
21Àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run;
22Ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkan búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù.
23Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìreti wa mu ṣinṣin ni àìsiyèméjì; (nítorí pé olóòtọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí).
24Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere:
25Kí a ma máa kọ ìpejọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni niyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ etílé.
26Nítorí bí àwa ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́sẹ̀ lẹ̀yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
27
28
29
30
31Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.
32Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti ṣi yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà;
33Lápakan, nígbà tí a ṣọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápakan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹ̀gbẹ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ si.
34Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.
35Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.
36Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní suuru, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.
37
38
39Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.