1Nítorí náà bí a ti fi ikúukùu àwọsánmà tí o kún fún àwọn ẹlẹ́ri tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tí si apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,
2
3Má a ro ti ẹni tí ó faradà irú sọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má baa rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
4Ẹ̀yin kò sáà tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀ nínú ìjakadi yín.
5
6
7Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í báwí?
8Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, njẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ.
9Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríbà fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè?
10Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o ba ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀.
11Gbogbo ìbáwí kò dábì ohun ayọ̀ nísinsìn yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹ́yìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12
13
14Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa:
15
16
17
18
19Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ si i fún wọn mọ́:
20
21
22Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Síónì, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerúsálémù ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn áńgẹ́lì àìníye,
23Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o
24
25
26
27Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.
28Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a ni oore-ọfẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́tẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀.
29