1Kí ìfẹ́ ará o wà títí.
2
3Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tikarayin pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.
4Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrin gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléérí: Nítorí àwọn àgbérè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ̀jọ́.
5
6
7Ẹ máa rántí àwọn ti wọn jẹ́ aṣáájú yín, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà-ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn.
8Jésù Kírísítì ọ̀kan náà ni lánà, àti lóní, àti títí láé.
9Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.
10Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.
11
12Nítorí náà Jésù pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ̀yìn ìbodè.
13Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ̀yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.
14Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níyin, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.
15
16Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín funni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ
17Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríbà fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀sọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìsírò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.
18Ẹ máa gbàdúrà fún wa: Nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo.
19Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.
20
21Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jésù Kírísítì; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín
22Èmi sì ń bẹ̀ yín ará, ẹ gbà ọ̀rọ̀ ìyànjú mi; nítorí ìwé kukuru ni mo kọ sí yín.
23Ẹ mọ pé a sá Timótéù arákùnrin wa sílẹ̀; bí ó ba tètè dé, èmí pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
24Ẹ ki gbogbo àwọn tí ń ṣe olórí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àwọn tí o ti Ítalì wá ki yín.
25Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.