1Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábàápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti Àpósítélì àti Olórí Àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jésù;
2
3Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mósè lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ.
4Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.
5
6Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.
7
8
9
10
11
12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.
13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjù ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnìkẹni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.
14Nítorí àwá di alábàápín pẹ̀lú Kírísítì, bí àwá bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin;
15
16
17
18Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn?
19Àwá sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.