1Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àti wọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má baà dà bí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀.
2Nítorí tí àwá gbọ́ ìwàásù ìyìn rere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní ire, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ.
3
4
5
6Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a tí wàásù ìyìn rere náà fún ní ìṣáajú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn:
7
8Nítorí, ìbá ṣe pé Jóṣúà tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ̀yìn náà,
9nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
10
11Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má baà ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.
12Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú-méjì lọ, ó sì ń gunni àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn.
13Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòòhò tí a sì ṣípayá fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.
14Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jésù ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin.
15Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì báni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́sẹ̀.
16Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ranni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.