1Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀.
2Ẹni tí ó lè bá àwọn aláìmòye àti àwọn tí ó ti yapa kẹ̀dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú.
3Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń se fún ara rẹ̀ náà.
4Ko sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò se ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Árọ́nì.
5
6
7
8Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ gbọ́ràn nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀;
9
10
11Nípa èyí àwá ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́.
12Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ní, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle.
13Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń mu wàrà jẹ́ aláìlóye ọ̀rọ̀ òdodo: nítorí ọmọ ọwọ́ ni.
14Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọn ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàrin rere àti búburú.