1Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Tìmótíù arákùnrin wa.
2
3
4Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Kírísítì, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
5Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń ṣàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà.
6tí ó ti wá sọ́dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrin yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ ọ́, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.
7
8ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
9
10Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹlẹ́gbẹ́ irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà ninú ìmọ̀ Ọlọ́run.
11pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀ṣíwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.
12Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yin láti jẹ́ alábàápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.
13
14Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, ìdàríjì ẹ̀sẹ̀.
15
16Nítorì nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.
17
18
19Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun lè máa gbé nínú rẹ̀.
20Àti nípaṣẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ lọ́rùn, nípa mímú àlàáfíà wá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélèbùú.
21Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín.
22Ṣùgbọ́n nísinsìnyìí, ó ti mú yín padà nípa ara rẹ̀ nìpa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti aláìlábùkù.
23Bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fesẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró sinsin, láláìyẹṣẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìyìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Pọ́ọ̀lù ṣe ìránṣẹ́ fún.
24Nísinsinyìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kírísítì fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ.
25
26
27Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fi hàn kí ni títóbi láàrin àwọn aláìkọlà, ní ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kírísítì ìrétí ògo nínú yín.
28Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kírísítì.
29Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lúgbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń sisẹ́ nínú mi.