1Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodékíà àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí.
2Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ lè ní ìjìnlẹ̀ ìrírí ìmọ́ Kírísítì pẹ̀lú òye àti ìmọ̀ tó dájú ṣáká. Nítorí nísinsinyìí, Ọlọ́run ti fi àṣírí ètò hàn. Ìjìnlẹ̀ àṣírí ètò náà ni Kírísítì fúnrarẹ̀.
3
4Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma baà fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín sìnà.
5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsí ètò yín àti bí ìdúró sinsin yín nínú Kírísítì ti rí.
6Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jésù Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.
7Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé e yín ró nínú rẹ̀, ẹ máa se alágbára nínú ìgbàgbọ́, bí a ti ṣe kọ́ ọ yín, àti kí ẹ sì máa ṣàn bí omi pẹ̀lú ọpẹ́.
8Ẹ máa kiyesii pé ẹnikẹ́ni kò fi ìmọ̀ àti ẹtan asan ko yín ní ìgbèkùn, èyí tí ó jẹmọ́ ìtàn ènìyàn bi ìpilẹ̀sẹ ẹ̀kọ́ ayé láìse ohun tí Kírísítì ti wí.
9Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara,
10
11Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì.
12Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.
13Àti ẹ̀yin, ẹni tí o ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ni, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín;
14Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn-án a mọ àgbélébùú;
15
16
17
18Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn ańgẹ́lì lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nipa èrò ti ọkan ara rẹ̀.
19
20
21Má ṣe dìímú, má se tọ́ ọ wò, má ṣe fọwọbàá,
22
23Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, ni àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọn-ara-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè hàn nínú fún ìfẹ́kúfẹ ara.