1
2Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lóké kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé.
3Nítorí ẹ̀yín ti kú, a sì fi iyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kírísítì nínú Ọlọ́run.
4Nígbà tí Kírísítì, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.
5Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyìí jásí ìbọ̀rìsà.
6Lórí àwọn wọ̀nyìí ni ìbínú Ọlọ́run ńbọ̀ wá.
7Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apákan ayé yìí.
8Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyìí sílẹ̀: ìbínú, ìrúnú, àránkan, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín.
9Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ayé yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀,
10
11Níbi tí kò gbé sí Gíríkì tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìnímọ̀, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kírísítì ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.
12
13Ẹ máa fara dàá fún ara yín, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kírísítì ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.
14Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.
15Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́.
16
17Ohunkóhun tí ẹ̀yín bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.
18
19Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.
20Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigi nínú Olúwa.
21Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.
22Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrojú ṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣugbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run:
23
24Kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè ogun: nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kírísítì.
25Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbàá padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì sí ojúṣáájú.