1
2
3
4Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀.
5
6Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un làti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.
7
8
9
10Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn ańgẹ́lì, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.
11Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin.
12
13Kí ni ẹ̀yìn fún ra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?
14Njẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.
15Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígún, ògo ni ó jẹ́ fùn un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún-ún.
16
17Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá pé jọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú.
18
19Kò sí àníàní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrin yín, kí àwọn tí ó yanjú láàrin yín le farahàn kedere.
20Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ.
21Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olukúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkèjì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara.
22Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kí ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.
23Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Júdásì fi hàn, Olúwa Jésù Kírísítì mú búrẹ́dí.
24Lẹ́yìn igbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.”
25
26
27Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú kọ́ọ̀bù Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.
28Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa kí ó tó jẹ lára àkàrà nàá àti kí ó tó mu nínú ife náà.
29Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú kọ́ọ̀bù láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kírísítì áti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín.
30Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń sàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn.
31Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáadáa, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́.
32
33Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúùgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbi fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín.
34