1Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè.
2
3
4Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni.
5Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni.
6Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n lọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣisẹ́ gbogbo wọn níní gbogbo wọn.
7Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè.
8Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn lámọ́ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mimọ́ kan náà ni èyì ti wá.
9Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwonisàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.
10
11Àní, Ẹ̀mi kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.
12
13
14Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.
15Tí ẹ̀ṣẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara.
16Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apákan ara,” èyí kò lènu máa jẹ́ apákan ara mọ́
17Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú? Níbo ni a ó ti ma gbọ́ràn? Tí gbogbo ara bá jẹ̀ etí ńkọ́? Ọ̀nà wo la lè gbà gbọ́ òórùn?
18Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.
19Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ìkanṣoṣo nínú ẹ̀yà-ara, níbo ni ara yóò gbé wà.
20Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.
21Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.”
22Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan-an ni a ko le ṣe aláìnílò.
23Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara ti a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara ti a rò pé yẹ rára ni àwa ń fi ipò ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ.
24Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ sọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní.
25Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn.
26Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.
27
28
29Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ àpósítélì bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí?
30Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Olọ́run fún lẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ̀n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí?
31Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara sàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.