1Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fí itará ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa ṣọ tẹ́lẹ̀.
2Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀;
3Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú.
4Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ìjọ múlẹ̀.
5Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa, pẹ̀lúpẹ̀lú láti lè máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ tóbi jú ẹni ti ń sọ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtúmọ̀, kí ijọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.
6Ǹjẹ nísinsìnyìí, ará, bí mo bá wá sí àárin yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmí óò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá iṣọtẹ́lẹ̀, tàbí nipá ẹ̀kọ́?
7Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìba à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí?
8Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun?
9Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹyin bá ń fí ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán.
10Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀
11Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ itúmọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó já sí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí já sí aláìgbédè sí mi.
12Bẹ́ẹ̀ si ní ẹ̀yín, bí ẹ̀yín ti ni itara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ síi fún ìdàgbàsókè ìjọ.
13Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ.
14Nítorí bí èmí bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkan mi jẹ́ aláìléso.
15
16
17Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítóótọ́, ṣùgbọ́n a kó fí ẹsẹ̀ ẹnikéjì rẹ múlẹ̀.
18Mó dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run tí èmi ń fọ̀ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ:
19Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fí ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹ̀lomíran ju ẹgbáarún ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀.
20
21
22Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n isọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.
23Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fí èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ̀kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹyin ń ṣe òmùgọ̀?
24Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbi tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.
25Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi aṣiri ọkan rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sín Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrin yín!”
26
27Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbi bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀,
28Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pá ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
29Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ.
30Bí a bá sì fí ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́.
31Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ́kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú.
32Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì.
33Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà.
34
35Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.
36Kí ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tabi ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá?
37Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tabí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkán wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé ofin Olúwa ni wọ́n.
38Ṣùgbọ́n bí ẹnikan bá fi ojú fo èyí dá, òun fún ra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.
39Nítorí náà ará, ẹ máa fí ìtara ṣáfẹrí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dànílẹ́kún láti fi èdè fọ̀.
40Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.