1Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìyinrere náà dí mímọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró.
2Nípaṣẹ̀ ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹyin kàn gbàgbọ́ lásán.
3
4
5
6Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fí di ìsinsìnyìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn.
7Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jèmísì; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn Àpósítélì.
8
9
10Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fí fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ̀pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.
11Nítorí náà ìbáà ṣe èmí tabí àwọn ni, bẹ́ẹ̀ ní àwa wàásù, bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́
12Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kírísítì pé ó tí jíǹdé kúró nínú òkú, è é há tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín ti wí pé, àjíǹde òkú kò sí.
13Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kírísítì kò jíǹde.
14
15Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kírísítì dìdé kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde?
16Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kírísítì dìdé,
17Bí a kò bá sì jí Kírísítì dìdé, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yín wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀.
18
19Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrétí nínú Kírísítì, àwa jásí òtòsì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.
20Ǹjẹ́ nísinsìnyìí Kírísítì tí jíǹde kúró nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn.
21
22
23
24Nígbá náà ni òpín yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pá gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run.
25
26Ikú ní ọ̀ta ìkẹ́yìn tí a ó párun
27
28
29Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọmi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamítíìsì wọn nítorí wọn?
30Nítorí kínní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo?
31Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kírísítì Jésù Olúwa wá pé, èmi ń kú lojoojúmọ.
32
33Kí a má tàn yín jẹ́: “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́!?”
34
35Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?”
36
37Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n irúgbín lásán ni, ìbáàṣe àlìkámà, tabi irú mìíràn.
38
39Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà: ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ.
40Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ: ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀.
41Ọ̀tọ̀ ni ògo ti òòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ sá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.
42
43A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì ji í dìde ní agbára.
44A gbìn ín ni ara ti ọkàn, a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.
45
46Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáajú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.
47Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá, ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.
48Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.
49Bí àwa ó sì rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àworán ẹni ti ọ̀run.
50Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.
51Kíyesí í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà,
52Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìdé ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.
53Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé àra àìkú wọ̀.
54
55
56Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin
57Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jésù Kírísítì!
58Nítorí náà ẹ̀yín ará mi olùfẹ́ẹ̀ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, níwọn bí ẹyin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.