1Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa gbéyàwó.
2Ṣùgbọ́n nítorí àgbérè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ̀ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀.
3Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀.
4Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀.
5
6Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ.
7
8Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọn kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà.
9
10Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.”
11Ṣùgbọ́n tí ó bá kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó padà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ ti ó fi sílẹ̀ àti ọkùnrin pàápàá kò gbọdọ̀ fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.
12
13Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
14Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kírísítì gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kírísítì gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.
15Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Onígbàgbọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin náà kò sí lábẹ́ idè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlààfíà.
16
17
18
19
20Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì.
21Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì.
22
23
24Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.
25Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúndíá: èmi kò ní aṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo.
26Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsinyìí, èyi nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí ẹ ṣe wà.
27Ṣùgbọ́n tí ó bá ti gbéyàwó tàbí tí ó bá ti lákòókó, ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí kò bá sì tí ì gbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáre láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákókó yìí.
28Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́sẹ̀, bí a bá gbé wúndíá ní ìyàwó òun kò dẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n mo dá a yín sí.
29
30àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí,
31àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí àṣà ayé yìí ń kọ́ja lọ.
32
33Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn ẹrù rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,
34dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí ó bá wà nílé ọkọ, irú ìṣòro kan náà ni ó dojú kọ. Ọmọbìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa ṣàkìtiyan láti tẹ́ Olúwa lọ́rùn ní gbogbo ìwà àti ìṣe àti ní tí ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe àkíyèsí ohun púpọ̀, yóò máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.
35Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbon kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.
36Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúndíá rẹ̀ bí ó bá ti di obìnrin, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́sẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó.
37Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró sinsin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọ́dọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lóri ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúndíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere.
38Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúndíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jù lọ.
39
40