1
2
3
4
5Nítorí pé bí ìjìyà Kírísítì ti sínú ayé wa,, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ pẹ̀lú nípa Kírísítì.
6Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbi bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù làti mú yin ní irú ìfaradá ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́.
7Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹyin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹyin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.
8Ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Éṣíà, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́.
9Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde:
10Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé pé yóò sí máa gbà wá ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀,
11Bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fí àdúrà yín ìràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere táa rí gbà nípa ìdáhún sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
12Nítorí èyí ní ìsògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú ìń jérìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní tumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
13Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí èyín kò lè kà mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé.
14Gẹ́gẹ́ bí ẹyín pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apákan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jésù Olúwa.
15Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnun láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jànfààní ìgbà méjì.
16
17Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbérò bẹ́ẹ̀, èmi há ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?
18Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòótọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni ati bẹ́ẹ̀ kọ́.
19
20
21Ǹjẹ́ níṣinṣin yìí, Ọlọ́run ni ó fí ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kírísítì, Òun ni ó ti fi àmì òróró yàn wá,
22ó sì fí èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.
23Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àtidá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọ́ríńtì.
24Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró sinisin.