1
2
3Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ rìn nípa ti ara, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara.
4Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀.
5Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbékùn wá sí ìtẹríba fún Kírísítì.
6
7
8Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fifún wá fún mímú yn ìdàgbàsókè, dípò fífa yín subú, ojú kí yóò tì mí.
9Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fí ìwé kíkọ dẹ́rùbá yín.
10
11Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.
12Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fí ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fí ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fí ara wọn wé ara wọn.
13Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín.
14Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìn rere Kírísítì.
15
16Kí a bà à lè wàásù ìyìn rere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.
17
18Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní itẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.