1Èmi kò lè sàì sògo bí kò tilẹ̀ ve àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípayá ti Olúwa fihàn mí.
2Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kírísítì ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yin, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ sí ọ̀run kẹta.
3Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀.
4
5Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkáraami èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi.
6Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi.
7
8Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi.
9Òun sì wí fún mi pé, “Oore ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fí ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kírísítì lè máa gbé inú mi.
10
11
12Ohun kan tí ó ṣe àmì àpósítélì, iṣẹ́ ìyanu and iṣẹ́ agbára ní won ṣe ní àárin yín pẹ̀lú sùúrù tó ga.
13Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnú fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.
14Kíyèsí i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò se àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.
15Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó há tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí?
16
17Èmi há rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi?
18
19Ẹ̀yin há rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń ṣọrọ nínú Kírísítì; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni.
20
21Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má bà à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbérè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.