1
2Ẹ̀yin fúnara yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.
3
4Irú ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ yìí ni àwa ní nípaṣẹ̀ Kírísítì sọ́dọ̀ Ọlọ́run:
5Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé làti ọ̀dọ̀ àwa tìkárawa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà;
6Ẹni tí ó mú wa tó bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú titun; kì í ṣe ní ti ìwé-àkọọ́lẹ̀ nítorí ìwé a máa pani, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ni dí ààyè.
7
8Yóò há ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?
9Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.
10Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.
11Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo.?
12Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.
13Kì í sì í ṣe bí Mósè, ẹni tí ó fí ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Ísríẹ́lì má baà lè tẹjú mọ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ
14Ṣùgbọ́n ojú-inú wọn fọ́; nítorí pé títí fí di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mu láéláé, ìbòjú kan náà sì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kírísítì ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.
15Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbákùúgbà ti a bá ń ka Mósè, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kan wọn.
16Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.
17
18Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjijì, a sì ń pawádà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.