1Nitorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí bí àwa ti rí ní iṣẹ́-ìránṣẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti fi àánú gbà, àárẹ̀ kò mú wá;
2Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífí òtítọ́ hàn, àwa ń fí ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run.
3Ṣùgbọ́n báyìí, bí iyinrere wa bá sí farasin, ó farasin fún àwọn tí ó ń ṣègbé.
4
5Nítórí àwa kò wàásù àwa tìkárawa, bí kò se Kírísítì Jésù Olúwa; àwa tikarawa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jésù.
6
7Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò àìmọ́, kí ọlá ńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.
8A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dàámú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù.
9A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.
10Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jésù Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jésù hàn pẹ̀lú lará wa.
11Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fí àwa tí ó wà láàyè fún ikú nítorí Jésù, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú.
12Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.
13
14
15Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọpẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
16Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, ṣíbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di túntún lójoojúmọ́.
17Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ kíún yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayè tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa.
18Níwọ̀n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.