1Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.
2Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá.
3Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòòhò.
4Nítorí àwa tí ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa yóò jẹ́ aláìwọsọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè baà lè gbé ara kíkú mì.
5Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèṣè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.
6Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.
7Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rírí.
8Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa.
9Nítorí náà àwa ń dù ú, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
10Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọ́dọ̀ fí ara hán níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kírísítì; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i ti ṣe nígbà tí ó wà nínú ara ìbáà ṣe rere tàbí búburú.
11Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fí wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hán ní ọkàn yín pẹ̀lú.
12
13Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá sí pépé, fún yín ni.
14
15Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láàyè má sì ṣe wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.
16Nítorí náà láti ìṣinṣin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kírísítì nípa ti ara, ṣùgbọ́n níṣinṣin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́.
17
18
19Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kírísítì, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́.
20
21