1Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedóníà;
2Bí ó ti jẹ́ pé dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti ìdégóńgó àìní wọn ti kún à kún wọ́ sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn.
3
4
5Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run.
6
7Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhun gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú.
8Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lé rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmírán.
9
10
11Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó baà lè ṣe pé, bí ìmúra tẹ́lẹ̀ fún ṣiṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín.
12Nítorí bí ìmúra tẹ́lẹ̀ bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní.
13Nítorí èmi kò fẹ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín. Ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba,
14Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àní ṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú baà lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba baà lè wà.
15
16Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Títù fún yín.
17Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkárarẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnra rẹ̀.
18
19
20Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má baà rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín.
21Àwa ń gbérò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.
22Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní isínsnyìí ni ìtara rẹ̀ túbọ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntàn ńlá tí ó ní sí yín.
23Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Títù jẹ́, ẹlẹ́gbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń bèèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kírísítì.
24Nítorí náà ẹ fí ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.