1
2Ìyìnrere tí a ti pinnu láti ẹnu àwọn wòlíì nínú ìwé Mímọ́ láti ìgbà pípẹ́ ṣáájú ìsinsin yìí.
3Nípa ìfiyèsí ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ ìran Dáfídì nípa ìbí ti ènìyàn.
4Ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹmi ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jésù Kírísítì Olúwa wa.
5
6Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jésù Kírísítì.
7
8
9Ọlọ́run, ẹni tí èmí ń sìn tí mo sì fi gbogbo ọkàn mi jìn fún un láti máa wàásù ìyìnrere ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsinmi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi
10
11Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa,
12èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.
13
14
15Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Róòmù àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìn rere Ọlọ́run sí i yín.
16
17
18
19Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn.
20
21
22Wọ́n Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá.
23
24Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́.
25Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń forí balẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.
26Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́ ìwàkíwà: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ yí ìlò àdánidá padà sí èyí tí ó lòdì sí ti àdánidá:
27Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìsìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.
28Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe:
29Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àránkan; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà-búburú; wọ́n jẹ́ afi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́.
30Asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, akóríra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí,
31Aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú:
32Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.