1Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan?
2
3Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyé, panṣagà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóòsì jẹ́ panṣagà, kódà bí ó bá ní ọkọ mìíràn.
4
5
6Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa kíkú láti ipasẹ̀ ohun tó so wápọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í se ní ìlànà ti àtijọ́ tí òfin gùnlé.
7
8
9Èmi sì ti wà láàyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú.
10
11Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí àyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin se ikú pa mi.
12
13Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.
14
15
16Ṣùgbọ́n bí mo bá se ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára.
17Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ se rí yìí kì í se èmi ni ó se é bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.
18Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ mi. Èmi fẹ́ se èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe.
19Níorí ohun tí èmi se kì í se ohun rere tí èmi fẹ́ láti se; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, éyí nì ni èmi ń se.
20Nísinsin yìí, bí mo bá ń se nǹkan tí n kò fẹ́ láti se, kì í se ẹ̀mi fúnra mi ni ó se é, bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó se é.
21Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ se rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi.
22
23
24
25Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa!