1Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe. Nísinsìnyìí, a bèèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jésù Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí.
2Nítorí pé, ẹyin mọ àṣẹ tí a pa fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jésù.
3
4
5kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run;
6àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni yín máa ṣe kùnà arákùnrin rẹ̀ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn níyà fún gbogbo ẹ̀sẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
7Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú àìmọ́, bí kò ṣe sínúìgbé-ayé mímọ́.
8Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í se òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.
9Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará a ò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín.
10Nitòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makidóníà. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀.
11
12Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í se Kírísítẹ́nì gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèṣè.
13
14
15Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láàyè, tí a sì kù lẹ́yìn de àtiwá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀.
16
17Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láàyè sókè nínú àwọ̀sánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé.
18Nítorí náà, ẹ tu ara yín nínú, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.