1
2
3
4Nítorí náà, àwa tìkara wa ń fi yín ṣògo nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà nínú gbogbo ìjọ.
5Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé ní torí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà.
6Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,
7Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì se nígbà ìfarahàn Jésù Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì alágbára.
8
9A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n níyà, a ó sì se wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀
10Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárin gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.
11
12Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jésù Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa.