1Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Fáráò, mo ti ṣé ọkàn Fáráò le àti ọkàn àwọn ìjòyè rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.
2Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yin àti àwọn ọmọ ọmọ yín; Bí mo ti jẹ àwọn ará Éjíbítì níyà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”
3Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, ti wọn sí wí fún pé, “Èyí ni OLÚWA, Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ: ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi?
4Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la.
5Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ.
6Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Éjíbítì. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mósè pẹ̀yìndà kúrò níwájú Fáráò.
7Àwọn ìjòyè Fáráò sọ fún “Yóò ti pẹ to tí ọkùnrin yìí yóò máa mú ìyọnu bá wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn OLÚWA Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí ṣíbẹ̀ pé, ilẹ̀ Éjíbítì ti parun tán?”
8Nígbà náà ni a mú Árónì àti Mósè padà wá sí iwájú Fáráò ó sì wí fún wọn pé “Ẹ lọ sìn OLÚWA Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”
9Mósè dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe ajọ fún OLÚWA.”
10Fáráò sì wí pé, “Mo fi OLÚWA búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín.
11Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin OLÚWA, ní wọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yín ń béèrè fún.” Wọ́n sì lé Mósè àti Árónì kúrò ní iwájú Fáráò.
12Ní ìgbà náà ni Ọlọ́run sọ fún Mósè, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè lórí Éjíbítì kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú bo gbogbo ilẹ̀, kí ó sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko wọn jẹ́, àní gbogbo ohun tí òjò yìnyín kò bájẹ́ tan.”
13Nígbà náà ni Mósè na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Éjíbítì, OLÚWA sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ Esú wá;
14
15Wọ̀n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tó kù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewe tí ó kù lórí igi tàbí lorí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Íjibítì.
16Fáráò yára ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú.
17Nísinsìnyìí ẹ dárí jín mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
18Nígbà náà ni Mósè kúrò ní iwájú Fáráò ó sì gbàdúrà sí OLÚWA.
19OLÚWA sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀ oòrùn wá láti gbá àwọn Esú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Éjíbítì lọ sínú òkun pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ Esú kan kò ṣẹ́ kù sí orí ilẹ̀ Éjíbítì.
20Ṣíbẹ̀ OLÚWA ṣe ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
21Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí okùnkùn báà le bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì; àní òkùnkùn biribiri.”
22
23Kò sí ẹni tí ó le è ríran rí ẹlòmíràn tàbí kí ó kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ̀ mẹ́ta. Ṣíbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ̀lì ni ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé.
24Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè ó sì wí fún un pé, “Lọ sìn OLÚWA, kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀.”
25Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Ìwọ gbọdọ̀ fún wa láàyè láti rúbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun ní iwájú OLÚWA Ọlọ́run wa.
26Àwọn ohun ọ̀sìn wa gbọdọ̀ lọ pẹ̀lú wa, a kì yóò fi pátákò ẹṣẹ̀ ẹran sílẹ̀. A ní láti lò lára wọn fún sínsìn OLÚWA Ọlọ́run wa, ìgbà tí a bá sì dé ibẹ̀ ni a ó to mọ̀ ohun ti a ó lò láti fi sìn OLÚWA.”
27Ṣùgbọ́n OLÚWA ṣé ọkàn Fáráò le, kò sì ṣetan láti jẹ́ kí wọn lọ.
28Fáráò sọ fún Mósè pé, “Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kú.”
29Mósè sì dáhùn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, “Èmi kí yóò wá sí iwájú rẹ mọ́.”