1Ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Élímù, wọ́n dé sí ijù Sínì tí ó wà láàrin Élímù àti Ṣínáì, ni ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.
2Ní ijù náà ni ìjọ àwọn ènìyàn ti kùn sí Mósè àti Árónì.
3
4
5Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”
6Mósè àti Árónì sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé OLÚWA ni ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.
7Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo OLÚWA, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”
8Mósè tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé OLÚWA ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ̀ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkún ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, OLÚWA ni ẹ̀yin kùn sí i.”
9Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pe, ‘Ẹ wá sí iwájú OLÚWA, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”
10Ó sì ṣe bí Árónì ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọn si bojúwo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo OLÚWA si farahàn ni àwọ̀-sánmọ̀.
11OLÚWA sọ fún Mósè pé,
12“Èmi ti gbọ́ kíkun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.’ ”
13Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká.
14Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsí i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀.
15
16Èyí ni ohun tí OLÚWA ti pàṣẹ: ‘Kí olúklùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì kan (bí i líta méjì) fún ẹnikọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ”
17Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré.
18
19Mósè sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwurọ̀ ọjọ́ kejì.”
20Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mósè bínú sí wọn.
21Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí òòrùn bá sì mú, a sì yọ́.
22Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń kó tẹ́lẹ̀: òṣùnwọn ómérì méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mósè.
23
24Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mósè ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin.
25Mósè sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi OLÚWA. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní.
26Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”
27Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó.
28OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́?
29Wò ó? OLÚWA ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni ounjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọọkan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.”
30Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.
31
32Mósè wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì mánà kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì.’ ”
33Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó mánà tí ó kún òṣùnwọ̀n ómérì kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú OLÚWA láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”
34Bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè, Árónì gbé mánà sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́.
35Àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ mánà fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kénánì ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ mánà títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbégbé Kénánì.
36(Ọ̀sùnwọn ómérì kan sì jẹ́ ìdákan nínú ìdá-mẹ́wàá éfà.)