Ìwé Ékísódù 17:1-16 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì si gbéra láti jáde kúrò láti ihà Sínì wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Réfídímù Ṣugbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú.

2Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mósè, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.”

2Mósè dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èése ti ẹ̀yin fi ń dán OLÚWA wò?”

3ⓑ Ṣùgbọ́n òùngbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Éjíbítì láti mú kí òùngbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òùngbẹ.”

4Nígbà náà ni Mósè gbé ohùn rẹ̀ sókè sí OLÚWA pé; “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”

5OLÚWA sì dá Mósè lóhùn pé, “Má a lọ ṣíwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Náìlì lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ.

6Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Hórébù. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mósè sì se bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.

7Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Másá (ìdánwò) àti Méríba (kíkùn) nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀, wọ́n sì dán OLÚWA wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ OLÚWA ń bẹ láàrin wa tàbí kò sí?”

8Àwọn ara Ámélékì jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Réfídímù.

9Mósè sì sọ fún Jọ́súà pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Ámélékì jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.”

10Jósúà se bí Mósè ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Ámélékì jagun; nígbà tí Mósè, Árónì àti Húrì lọ sí orí òkè náà.

11Níwọ̀n ìgbà tí Mósè bá gbé apá rẹ̀ sókè, Ísírẹ́lì n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Ámélékì a sì borí.

12Ṣùgbọ́n apá ń ro Mósè; Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà: Árónì àti Húrì sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti òòrùn wọ.

13Jósúà sì fi ojú idà sẹ́gun àwọn ará Ámélékì.

14ⓒ  OLÚWA sì sọ fun Mósè pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Jóṣúà pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìràntí Ámélékì run pátapáta kúrò lábẹ́ ọ̀run.”

15Mósè sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní OLÚWA ni àṣíá mi (Jóhéfà-Nisì).

16Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ OLÚWA. OLÚWA yóò bá Ámélékì jagun láti ìran dé ìran.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>