Ìwé Ékísódù 18:1-27 BYB2014 - Bible AI

1Jẹ́tírò, àlùfáà Mídíánì, àna Mósè, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí OLÚWA ti mú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti Éjíbítì wá.

2Nígbà náà ni Jẹ́tírò mu aya Mósè tí í se Ṣípórà padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (Nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀).

3ⓐ Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gésómù (àjòjì); nítorí Mósè wí pé, “Èmi ń se àlejò ni ilẹ̀ àjòjì.”

4Èkejì ń jẹ́ Élíásérì (alátìlẹ́yìn); ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Fáráò.”

5Jẹ́tírò, àna Mósè, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mósè tọ̀ ọ́ wá nínú ihà tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run.

6Jẹ́tírò sì ti ránṣẹ́ sí Mósè pé, “Èmi Jẹ́tírò, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.”

7Mósè sì jáde lọ pàdé rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n kí ara wọn, wọ́n yọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ.

8Mósè sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti OLÚWA tí se sí Fáráò àti àwọn ará Éjíbítì nítorí Ísírẹ́lì. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí OLÚWA ti gbà wọ́n là.

9Inú Jẹ́tírò dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti OLÚWA ṣe fún Ísírẹ́lì, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

10Jẹ́tírò sì wí pé, “Ìyìn ni fún OLÚWA, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, ẹni tí ó sì gbà àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì.

11Mo mọ nísinsìnyìí pé OLÚWA tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Éjíbítì.”

12Jẹ́tírò, àna Mósè, mú ọrẹ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Árónì àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì sì wá láti bá àna Mósè jẹun ní iwájú Ọlọ́run.

13Ní ọjọ́ kejì, Mósè jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mósè fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.

14Nígbà tí àna Mósè rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń se sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jòkóò gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”

15Mósè dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run.

16Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrin ẹnìkín-ín-ní àti ẹnikejì, èmi a sì máa mú wọn mọ ofin àti ìlànà Ọlọ́run.”

17Àna Mósè dá a lóhùn pé, “Ohun ti o ń ṣe yìí kò dára.

18Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀ jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe

19Nísinsìnyìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè àìyedè wá sí iwájú rẹ̀.

20Kọ́ wọn ní ofin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà bí Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe.

21Sà àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n se olórí: lórí ẹgbẹ̀rún-ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-un, àádọ́ta-àádọ́ta àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.

22Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe.

23Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni ìtẹ́lọ́rùn.”

24Mósè fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un.

25Mósè sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kun ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì; ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rùn, ọgọ́rùn ún ọgọ́rùn ún, àádọ́ta-àádọ́ta, àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.

26Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mósè wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fún rawọn

27Mósè sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jẹ́tírò sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>